BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Ìtàn Mánigbàgbé nípa Olorì Luwoo Gbagida, obìnrin tó ṣáájú àsìkò rẹ̀ jẹ Ooni Ife tó sì tún jẹ́ alágbára nílẹ̀ Yorùbá
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn to pọ̀ lóde kò fi bẹ́ẹ̀ dárúkọ rẹ̀, nítorí pé ìtàn àtẹnudẹ̀nu ló pọ̀jù nínú ìtàn orile-ede Naijiria, ọ̀pọ̀ sí ló máa ń sọ ìtàn bí ẹni pé ọkùnrin nìkan ló n jẹ Ooni Ife.
Àwọn aṣojú-ṣòfin tó wà níjọba wọlé ìbò abẹ́nú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo, àwọn alátakò fọnmú pé Tinubu ń ṣàtìlẹ́yìn fún wọn
Ti ẹ o ba gbagbe, awọn Oludije kan ṣe ifẹhonuhan niwaju ile ẹgbẹ wọn to wa niluu Ibadan ni ọjọ kẹrinla oṣu karun ọdun t'awa yii lasiko ti alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ ba gbogbo awọn oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC naa sọrọ.
Lẹ́yìn ò rẹyìn, Mahmoud Sadis Buba, tó mi orí ayélujára tìtì yọwọ́ nínú ètò ìdìbò 2027, ṣàlàyé ìdí abájọ
Buba sọ pe igbesẹ oun lati ma dije mọ fun ipo aṣoju-ṣofin l'Abuja wa ni ibamu pẹlu nnkan ti ẹgbẹ oṣelu APC fẹ.
Ogun Ukraine ló sọ mí di ẹni tó ń bá èèyàn gbé oyún
Ijíba Ukraine ko fẹ ki awọn ọmọ orilẹede rẹ maa ba awọn ọmọ ilẹ okere gbe oyun mọ.
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria àti Amẹrika gbẹ̀mí igbákejì ẹgbẹ́ ISIS, Abu-Bilal al-Minuki
Ọrọ yii lo n jẹyọ lẹyin ti Aarẹ ilẹ Amẹrika, Donald Trump ti kọkọ kede igbesẹ naa.
Fídíò, Olaniyan 'Idamu Industry' Oluwatosin jẹ́wọ́ pé ẹnu nìkan kọ́ lòun ní lórí ètò 'Ṣé o láyà?', Duration 2,21
Ẹ wa nnkan fidi le lati gbadun awọn idahun Idamu Industry lori ibeere ti BBC Yoruba bi i lori eto wa, Ṣó o Láyà.
Agbébọn tún yabo ilé ẹ̀kọ́ méjì ní Borno, jí ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ
Lọjọ kan naa ati asiko kan naa ti agbebọn n ṣoro ni Borno ni wọn tun n ko girigiri ba awọn eeyan l'Ahoro-Esinele, Ogbomoso nipinlẹ Oyo.
Kóòtù sọ Blessing CEO sí àhámọ́, fún ẹ̀sùn lílu jìbìtì N36m
Ile ẹjọ giga ilu Eko to wa n'Ikoyi, niwaju Adajọ D.I. Dipeolu ni Blessing to kede pe oun ni arun jẹjẹrẹ laipẹ yii ti farahan.
Fídíò, Agbolé Akọni: Mọ̀ nípa Ogboriefon, akọni tí wọ́n rí he lórí àkìtàn tó di jagunjagun ńlá, Duration 5,24
Lori eto Agbole Akọni BBC News Yoruba, idile Ogboriefon ni ilu Ibadan ni a balẹ si lati mọ nipa bi akọni yii ṣe lo igbesi aye rẹ nigba to wa laye.
Ààrùn Ebola tún gbòde, gbẹ̀mí èèyàn 65
Ajọ Centres for Diseases Control and Prevention ni Africa, CDC sọ pe eeyan 246 ni wọn ti ṣawari rẹ pe o lugbadi aarun naa, ti wọn si ṣe akọọlẹ iku eeyan marundinlaadọrin (65) ni agbegbe Mongwalu ati Rwanpara.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,55
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Làásìgbò bẹ́ sílẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC Oyo, wọ́n ba ilé ẹgbẹ́, dúkìá àwọn olùdíje sípò gómìnà jẹ́
Iroyin ni awọn ọmọ ẹgbe oṣelu APC ti inu n bi pẹlu awọn nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ ni wọn lọ sile ẹgbẹ naa ti wọn si lọ da nnkan ru.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ajínigbé fi ayédèrú iṣẹ́ tàn mi lọ sí Zamfara, wọ́n tún fowó ọkọ̀ ránṣẹ́ kí n lè tètè wá - Akẹ́kọ̀ọ́jáde Fásitì
Ọna keyeefi ti eeyan ko le rokan rẹ ni awọn ajinigbe naa gba pitu ọwọ wọn fun Arum Azi to kẹkọọ gboye ni Yunifasiti Jos, ipinlẹ Plateau.
Ọ̀pọ̀ èrò n‘Ibadan fẹ̀sùn ajínigbé kan Dókítà kan, wọ́n fẹ́ lú ú pa, dáná sun ọkọ̀ rẹ̀, ọ̀pẹ́ ọlọ́pàá tó dé sásìkò
Dokita naa ti a gbọ gbe o wale lati Amẹrika lawọn eeyan kan sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa to wa lagbegbe Eleyele wi pe awọn eeyan kan ti fẹ dana sun lagbegbe Ologuneru.
Wo kókó ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour tí wọn fi ní kí Olóòtú Ìjọba UK kọ̀wé fipò sílẹ̀
Lẹyin ipade ọjọ Iṣẹgun ni Akọwe ilegbee, Steve Reed ati akọwe ijọba fun ọrọ iṣẹ ati owo ifẹyinti, Pat McFadden, sọ pe awọn si wa lẹyin Olootu Ijọba.
Àwọn agbébọn mẹ́ẹ̀dógún ya wọ agboolé táwọn ilégbèé wà ní Ijebu-Ode, jí èèyàn mẹ́ta gbé lọ
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn afurasi agbebọn ti iye wọn fẹ ẹ to mẹẹdogun ni wọn yabo ibugbe Ipojo Golden Estate to w ani agbegbe Oke-Eri ni nnkan bii aago meje irọlẹ pẹlu awọn ohun ija gidi.
Ẹgbẹ́ alákatakítí ISIS, Al Shabaab àti Al Qaeda tí a lé ní Iraq àti Syria, ti fi ìwọ̀ oòrùn Afrika ṣe ibùba – Ìjọba Amẹrika kìlọ̀
Amẹrika ni afojusun oun ni lati ri pe awọn agbesunmọmi to n ṣọṣẹ ni Afrika ko lagbara to lati ṣe ikọlu si oun tabi awọn ti oun ni ibaṣẹpọ pẹlu ni Afrika.
Olùkọ́ fásítì tí wọ́n lù, yẹ̀yẹ́ níta gbangba pé ó ń bá akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀ ní yàrá ìkàwé, ohun tí a mọ̀ rèé
Koda, iroyin sọ pe Alufaa ijọ Aguda ti a mọ si Katoliiki ni ọkunrin ti wọn n lu ninu fidio naa.
Ìdí rèé tí ẹgbẹ́ òṣèlú NDC fi gbé ipò Ààrẹ sí ìhà gúúsù lọ́dún 2027, Peter Obi ni olùdíje ààrẹ, èmi ni igbákejì rẹ̀ - Kwankwaso
Kwankwaso, ti oun ati Peter Obi fi ẹgbẹ oṣelu ADC silẹ lọ sinu NDC lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise.
Lẹ́yìn tí ajínigbé gba N50m owó ìtúsílẹ̀, wọn pa àgbà olóṣèlú lẹ́gbẹ́ ADC, fi òkú rẹ̀ ránṣẹ́
Iroyin ni ọgọrun-un miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun gẹgẹ bi owo itusilẹ ki wọn to din owo naa ku si aadọta miliọnu naira.
Àlàyé rèé lórí ìdí tí ọkọ̀ òfurufú tó ń bọ̀ láti Amẹ́ríkà, tó yẹ kó balẹ̀ l‘Eko padà láì já èrò inú rẹ̀, lẹ́yín tó dúró fún wákàtí mẹ́jọ lójú òfurufú
Iroyin ni awọn ero inu ọkọ ofurufu naa lo ọpọ wakati loju ofurufu ni ọjọ Abamẹta naa to si jẹ pe wọn ni lati pada si ibi ti wọn ti n bọ bii ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa ṣe ṣadede wọgile irinajo ọhun lai sọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.
Ṣé lóòótọ́ ni àdó olóró tí ológun Chad jù fún Boko Haram pa ọ̀pọ̀ apẹja ọmọ Naijiria?
Ikọlu yii n waye lẹyin ọjọ diẹ ti ikọ agbesunmọmi Boko Haram kọlu ileeṣẹ ologun Chad nigba meji.
Láì ṣe IVF, obìnrin kan bímọ márùn-ún lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lẹ́yìn tó fi ọdún méjìlá yàgàn
Ohun to jẹ kayeefi ju ninu ọrọ rẹ ni pe Bedriya ko lo ilana iloyun igbalode; 'In Vitro Fertilization' (IVF) to fi loyun awọn ọmọ marun-un yii.
Àlàyé rèé lórí ohun fà á táwọn òṣìṣẹ́ tó ń pèsè omi àti ètò ọ̀gbìn ṣe gunle ìyánṣẹ́lódì
Akọroyin BBC News Yoruba wa nibi iwọde naa, to si bawọn osisẹ, alasẹ ileeẹsẹ ati awọn adari ẹgbẹ osisẹ nipinlẹ Kwara sọrọ lati mọ ohun to sokunfa iwọde naa.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Kí ló mú kí ọkọ̀ kan ré bọ́ láti orí afárá sí ìsàlẹ̀ èyí tó pa èèyàn mọ́kànlá l‘Ogun?
FRSC ṣalaye pe ọkọ Toyota kan ti nọmba rẹ jẹ GGE722KJ gbe okiti ni ẹẹmẹta ko to di pe o jabọ lati ori afara to wa.
"Eko Bridge yóò wà ní títìpa fún àtúnṣe láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun" -Ìjọba Eko
Eredi titipa naa bi wọn wi ni fun atunṣe, aabo ati iwadii
Èèyàn mẹ́ta tí ẹ̀yà ara pè níjà bọ́ sọ́wọ́ NDLEA fún ẹ̀sùn òògùn olóró
Femi Babafemi ti i ṣe Adari ikede ni NDLEA, ṣalaye ninu atẹjade naa pe baba agba ẹni ọgọta ọdun (60), torukọ rẹ n jẹ Romanus Nwabara, wa lara awọn akanda ẹda ti ọwọ ba fun ẹsun naa.
Ọkọ ojú omi tí wọ́n ti ṣàwárí ààrùn hantavirus balẹ̀ sí Spain, àyẹ̀wò bẹ̀rẹ̀ fáwọn èrò
Minisita feto ilera Spain, Mónica Gracía sọ pe bí wọn ṣe n ko awọn eeyan bọlẹ ninu ọkọ naa lo n lọ ni mẹsọmẹsọ amọ gbogbo awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi MS Hondius ni ko ṣoju pe ohunkohun n ṣe wọn.
EFCC kéde wíwá Sadiya Farouq, mínísítà tẹ́lẹ̀ fún ètò ìbojú-àánú wo aráàlú
Awọn ẹsun bii kiko owo ilu si apo ara ẹni, aṣilo ipo ati igbimọ pọ huwa ọdaran ni EFCC kede pe oun n wa Sadiya Farouq fun.
Ẹgbẹ́ NDC kéde ipò ààrẹ sí Gúúsù Naijiria ní 2027, 2031 fún Àríwá
Ikede yii waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹsan-an oṣu Karun-un ọdun 2026, nibi ipade apapọ ẹgbẹ NDC to waye niluu Abuja.
Kí ló dé tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń bá Gómìnà Seyi Makinde ṣiṣẹ́ níjọba ìpínlẹ̀ Oyo ń kọ̀wé fipò sílẹ̀?
Ohun ti ọpọ awọn to ti kọwe fipo silẹ sọ ni wi pe ija to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo ṣe idiwo fun awọn ninu eyo idibo to n bọ.
Lateef Adedimeji kéde orúkọ àwọn ìbẹ́ta rẹ àti ọjọ́ tí wẹ̀jẹwẹ̀mu ìdúpẹ́ yóò wáyé
Lateef Adedimeji ni aworan awọn ọmọ kan tawọn kan n gbe kaakiri ori ayelujara ti wọn n pe ni ọmọ oun kii ṣe ọmọ oun o, bi asiko ba to oun ati iyawo oun yoo fi fọto awọn ọmọ naa sita.
Ta ni Stanley Osifo tó fẹ́ kojú Tinubu níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC?
Bayii ọkunrin kan ti jade, to si ti ra fọọmu lati dije tako Tinubu nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC to n bọ nibi ti wọn ti maa yan awọn to gbe asia ẹgbẹ oṣelu naa nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Amotekun nawọ́ gán afurasí agbéṣùmọ̀mí ní ìpínlẹ̀ Ondo
Adeleye sọ pe ọwọ tẹ awọn afurasi naa lasiko tawọn Amotekun ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo mii latari italolobo kan ti wọn gbọ.













































































